Jeremiah 51:57
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí, àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ àti àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀, wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́,” ní ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Jeremiah 51:57 in English
Jeremiah 51:57 · Berean Standard Bible
I will make her princes and wise men drunk, along with her governors, officials, and warriors. Then they will fall asleep forever and not wake up,” declares the King, whose name is the LORD of Hosts.
Context
55Nítorí pé Olúwa ti ṣe Babeli ní ìjẹ,
ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀;
àwọn ọ̀tá wọn sì ń hó bi omi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn. 56Nítorí pé afiniṣèjẹ dé sórí rẹ̀,
àní sórí Babeli;
a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn:
nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa,
yóò san án nítòótọ́. 57Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí,
àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀
àti àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀,
wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́,”
ní ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 58Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Odi Babeli gbígbòòrò ní a ó wó lulẹ̀ pátápátá,
ẹnu-bodè gíga rẹ̀ ní a ó sì fi iná sun:
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ṣiṣẹ́ lásán,
àti àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣiṣẹ́ fún iná,
tí àárẹ̀ sì mú wọn.” 59Ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì pàṣẹ fún Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, nígbà tí o ń lọ ni ti Sedekiah, ọba Juda, sí Babeli ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Seraiah yìí sì ní ìjòyè ibùdó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.