Jeremiah 51:59
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì pàṣẹ fún Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, nígbà tí o ń lọ ni ti Sedekiah, ọba Juda, sí Babeli ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Seraiah yìí sì ní ìjòyè ibùdó.
Jeremiah 51:59 in English
Jeremiah 51:59 · Berean Standard Bible
This is the message that Jeremiah the prophet gave to the quartermaster Seraiah son of Neriah, the son of Mahseiah, when he went to Babylon with King Zedekiah of Judah in the fourth year of Zedekiah’s reign.
Context
57Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí,
àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀
àti àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀,
wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́,”
ní ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 58Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Odi Babeli gbígbòòrò ní a ó wó lulẹ̀ pátápátá,
ẹnu-bodè gíga rẹ̀ ní a ó sì fi iná sun:
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ṣiṣẹ́ lásán,
àti àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣiṣẹ́ fún iná,
tí àárẹ̀ sì mú wọn.” 59Ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì pàṣẹ fún Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, nígbà tí o ń lọ ni ti Sedekiah, ọba Juda, sí Babeli ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Seraiah yìí sì ní ìjòyè ibùdó. 60Jeremiah sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ ibi tí yóò wá sórí Babeli sínú ìwé kan, àní gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a kọ sí Babeli. 61Jeremiah sì sọ fún Seraiah pé, “Nígbà tí ìwọ bá dé Babeli, kí ìwọ kí ó sì wò, kí ìwọ kí ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.