Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jeremiah sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ ibi tí yóò wá sórí Babeli sínú ìwé kan, àní gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a kọ sí Babeli.

Jeremiah 51:60 in English

Jeremiah 51:60 · Berean Standard Bible

Jeremiah had written on a single scroll about all the disaster that would come upon Babylon—all these words that had been written concerning Babylon.

Context

58Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Odi Babeli gbígbòòrò ní a ó wó lulẹ̀ pátápátá, ẹnu-bodè gíga rẹ̀ ní a ó sì fi iná sun: tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ṣiṣẹ́ lásán, àti àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣiṣẹ́ fún iná, tí àárẹ̀ sì mú wọn.” 59Ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì pàṣẹ fún Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, nígbà tí o ń lọ ni ti Sedekiah, ọba Juda, sí Babeli ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Seraiah yìí sì ní ìjòyè ibùdó. 60Jeremiah sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ ibi tí yóò wá sórí Babeli sínú ìwé kan, àní gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a kọ sí Babeli. 61Jeremiah sì sọ fún Seraiah pé, “Nígbà tí ìwọ bá dé Babeli, kí ìwọ kí ó sì wò, kí ìwọ kí ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 62Kí ìwọ kí ó sì wí pé, ‘Olúwa ìwọ ti sọ̀rọ̀ sí ibí yí, láti ké e kúrò, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀, àti ènìyàn àti ẹran, nítorí pé yóò di ahoro láéláé.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.