Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé afiniṣèjẹ dé sórí rẹ̀, àní sórí Babeli; a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn: nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa, yóò san án nítòótọ́.

Jeremiah 51:56 in English

Jeremiah 51:56 · Berean Standard Bible

For a destroyer is coming against her— against Babylon. Her warriors will be captured, and their bows will be broken, for the LORD is a God of retribution; He will repay in full.

Context

54“Ìró igbe láti Babeli, àti ìparun láti ilẹ̀ àwọn ará Kaldea! 55Nítorí pé Olúwa ti ṣe Babeli ní ìjẹ, ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀; àwọn ọ̀tá wọn sì ń hó bi omi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn. 56Nítorí pé afiniṣèjẹ dé sórí rẹ̀, àní sórí Babeli; a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn: nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa, yóò san án nítòótọ́. 57Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí, àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ àti àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀, wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́,” ní ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 58Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Odi Babeli gbígbòòrò ní a ó wó lulẹ̀ pátápátá, ẹnu-bodè gíga rẹ̀ ní a ó sì fi iná sun: tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ṣiṣẹ́ lásán, àti àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣiṣẹ́ fún iná, tí àárẹ̀ sì mú wọn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.