Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìró igbe láti Babeli, àti ìparun láti ilẹ̀ àwọn ará Kaldea!

Jeremiah 51:54 in English

Jeremiah 51:54 · Berean Standard Bible

“The sound of a cry comes from Babylon, the sound of great destruction from the land of the Chaldeans!

Context

52“Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fínfín rẹ̀, àti àwọn tí ó gbọgbẹ́ yóò sì máa kérora já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀. 53Bí Babeli tilẹ̀ gòkè lọ sí ọ̀run, bí ó sì ṣe ìlú olódi ní òkè agbára rẹ, síbẹ̀ àwọn afiniṣèjẹ yóò ti ọ̀dọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá,” ní Olúwa wí. 54“Ìró igbe láti Babeli, àti ìparun láti ilẹ̀ àwọn ará Kaldea! 55Nítorí pé Olúwa ti ṣe Babeli ní ìjẹ, ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀; àwọn ọ̀tá wọn sì ń hó bi omi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn. 56Nítorí pé afiniṣèjẹ dé sórí rẹ̀, àní sórí Babeli; a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn: nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa, yóò san án nítòótọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.