Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé Olúwa ti ṣe Babeli ní ìjẹ, ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀; àwọn ọ̀tá wọn sì ń hó bi omi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn.

Jeremiah 51:55 in English

Jeremiah 51:55 · Berean Standard Bible

For the LORD will destroy Babylon; He will silence her mighty voice. The waves will roar like great waters; the tumult of their voices will resound.

Context

53Bí Babeli tilẹ̀ gòkè lọ sí ọ̀run, bí ó sì ṣe ìlú olódi ní òkè agbára rẹ, síbẹ̀ àwọn afiniṣèjẹ yóò ti ọ̀dọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá,” ní Olúwa wí. 54“Ìró igbe láti Babeli, àti ìparun láti ilẹ̀ àwọn ará Kaldea! 55Nítorí pé Olúwa ti ṣe Babeli ní ìjẹ, ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀; àwọn ọ̀tá wọn sì ń hó bi omi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn. 56Nítorí pé afiniṣèjẹ dé sórí rẹ̀, àní sórí Babeli; a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn: nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa, yóò san án nítòótọ́. 57Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí, àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ àti àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀, wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́,” ní ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.