Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Apó-ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a ṣí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn.

Jeremiah 5:16 in English

Jeremiah 5:16 · Berean Standard Bible

Their quivers are like open graves; they are all mighty men.

Context

14Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí: “Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná, àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun. 15Háà, ẹ̀yin ilé Israẹli,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè láti ọ̀nà jíjìn dìde sí i yín Orílẹ̀-èdè àtijọ́ àti alágbára nì àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ. 16Apó-ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a ṣí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn. 17Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ, àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ, wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ. Pẹ̀lú idà ni wọn ó run ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé. 18“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “Èmi kì yóò pa yín run pátápátá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.