Jeremiah 5:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Háà, ẹ̀yin ilé Israẹli,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè láti ọ̀nà jíjìn dìde sí i yín Orílẹ̀-èdè àtijọ́ àti alágbára nì àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ.
Jeremiah 5:15 in English
Jeremiah 5:15 · Berean Standard Bible
Behold, I am bringing a distant nation against you, O house of Israel,” declares the LORD. “It is an established nation, an ancient nation, a nation whose language you do not know and whose speech you do not understand.
Context
13Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́,
ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn.
Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.” 14Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí:
“Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí;
Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná,
àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun. 15Háà, ẹ̀yin ilé Israẹli,” ni Olúwa wí,
“Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè láti ọ̀nà jíjìn dìde sí i yín
Orílẹ̀-èdè àtijọ́ àti alágbára nì
àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀,
tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ. 16Apó-ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a ṣí
gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn. 17Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ,
àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin,
wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ,
wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ.
Pẹ̀lú idà ni wọn ó run
ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.