Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí: “Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná, àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun.

Jeremiah 5:14 in English

Jeremiah 5:14 · Berean Standard Bible

Therefore this is what the LORD God of Hosts says: “Because you have spoken this word, I will make My words a fire in your mouth and this people the wood it consumes.

Context

12Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa; wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan! Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá; àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn. 13Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́, ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn. Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.” 14Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí: “Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná, àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun. 15Háà, ẹ̀yin ilé Israẹli,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè láti ọ̀nà jíjìn dìde sí i yín Orílẹ̀-èdè àtijọ́ àti alágbára nì àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ. 16Apó-ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a ṣí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.