Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa; wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan! Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá; àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn.

Jeremiah 5:12 in English

Jeremiah 5:12 · Berean Standard Bible

They have lied about the LORD and said: “He will not do anything; harm will not come to us; we will not see sword or famine.

Context

10“Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run, ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá. Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa. 11Ilé Israẹli àti ilé Juda ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,” ni Olúwa wí. 12Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa; wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan! Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá; àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn. 13Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́, ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn. Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.” 14Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí: “Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná, àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.