Jeremiah 5:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ilé Israẹli àti ilé Juda ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,” ni Olúwa wí.
Jeremiah 5:11 in English
Jeremiah 5:11 · Berean Standard Bible
For the house of Israel and the house of Judah have been utterly unfaithful to Me,” declares the LORD.
Context
9Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?”
ni Olúwa wí.
“Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi
lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí? 10“Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run,
ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá.
Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,
nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa. 11Ilé Israẹli àti ilé Juda
ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,”
ni Olúwa wí. 12Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa;
wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan!
Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá;
àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn. 13Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́,
ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn.
Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.