Jeremiah 5:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí?
Jeremiah 5:9 in English
Jeremiah 5:9 · Berean Standard Bible
Should I not punish them for these things?” declares the LORD. “Should I not avenge Myself on such a nation as this?
Context
7“Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́?
Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀
àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.
Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn,
síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà
wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè. 8Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó,
tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn. 9Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?”
ni Olúwa wí.
“Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi
lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí? 10“Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run,
ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá.
Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,
nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa. 11Ilé Israẹli àti ilé Juda
ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.