Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó, tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn.

Jeremiah 5:8 in English

Jeremiah 5:8 · Berean Standard Bible

They are well-fed, lusty stallions, each neighing after his neighbor’s wife.

Context

6Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n, ìkookò aginjù yóò sì pa wọ́n run, ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, nítorí àìgbọ́ràn yín pọ, ìpadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀. 7“Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀ àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra. Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn, síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè. 8Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó, tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn. 9Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí? 10“Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run, ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá. Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.