Jeremiah 5:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ, àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ, wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ. Pẹ̀lú idà ni wọn ó run ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé.
Jeremiah 5:17 in English
Jeremiah 5:17 · Berean Standard Bible
They will devour your harvest and food; they will consume your sons and daughters; they will eat up your flocks and herds; they will feed on your vines and fig trees. With the sword they will destroy the fortified cities in which you trust.”
Context
15Háà, ẹ̀yin ilé Israẹli,” ni Olúwa wí,
“Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè láti ọ̀nà jíjìn dìde sí i yín
Orílẹ̀-èdè àtijọ́ àti alágbára nì
àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀,
tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ. 16Apó-ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a ṣí
gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn. 17Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ,
àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin,
wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ,
wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ.
Pẹ̀lú idà ni wọn ó run
ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé. 18“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “Èmi kì yóò pa yín run pátápátá. 19Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa?’ Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, ‘Ẹ̀yin ti kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín. Nísinsin yìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.