Jeremiah 49:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,” ni Olúwa wí.
Jeremiah 49:6 in English
Jeremiah 49:6 · Berean Standard Bible
Yet afterward I will restore the Ammonites from captivity,*” declares the LORD.
Context
4Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣògo nínú àfonífojì rẹ,
ṣògo nínú àfonífojì rẹ fún èso?
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ammoni aláìṣòótọ́,
ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé,
‘Ta ni yóò kò mí lójú?’ 5Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ
láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,”
ni Olúwa, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 6“Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan
tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,”
ni Olúwa wí. 7Nípa Edomu.
Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani?
Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè?
Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí? 8Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò,
ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani,
nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau,
ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.