Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nípa Edomu. Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani? Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè? Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?

Jeremiah 49:7 in English

Jeremiah 49:7 · Berean Standard Bible

Concerning Edom, this is what the LORD of Hosts says: “Is there no longer wisdom in Teman? Has counsel perished from the prudent? Has their wisdom decayed?

Context

5Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,” ni Olúwa, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 6“Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,” ni Olúwa wí. 7Nípa Edomu. Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani? Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè? Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí? 8Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò, ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani, nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau, ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò. 9Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá; ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀? Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò ní kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.