Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣògo nínú àfonífojì rẹ, ṣògo nínú àfonífojì rẹ fún èso? Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ammoni aláìṣòótọ́, ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé, ‘Ta ni yóò kò mí lójú?’

Jeremiah 49:4 in English

Jeremiah 49:4 · Berean Standard Bible

Why do you boast of your valleys— your valleys so fruitful,* O faithless daughter? You trust in your riches and say, ‘Who can come against me?’

Context

2Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí; “nígbà tí èmi yóò mú kí a gbọ́ ìdágìrì ogun ní Rabba tí Ammoni; yóò sì di òkìtì ahoro, gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná. Nígbà náà ni Israẹli yóò lé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde,” ni Olúwa wí. 3“Hu, ìwọ Heṣboni, nítorí Ai tí rún! Kígbe ẹ̀yin olùgbé Rabba! Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀. Ẹ sáré sókè sódò nínú ọgbà, nítorí Malkomu yóò lọ sí ìgbèkùn, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀. 4Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣògo nínú àfonífojì rẹ, ṣògo nínú àfonífojì rẹ fún èso? Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ammoni aláìṣòótọ́, ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé, ‘Ta ni yóò kò mí lójú?’ 5Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,” ni Olúwa, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 6“Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.