Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Hasori yóò di ibi ìdọdẹ àwọn akátá, ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé, kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.”

Jeremiah 49:33 in English

Jeremiah 49:33 · Berean Standard Bible

“Hazor will become a haunt for jackals,* a desolation forever. No one will dwell there; no man will abide there.”

Context

31“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀-èdè tí ó wà nínú ìrọ̀rùn, èyí tí ó gbé ní àìléwu,” ní Olúwa wí. “Orílẹ̀-èdè tí kò ní odi tàbí irin, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń dágbé. 32Àwọn ìbákasẹ á di ẹrù àti àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n á di ìkógun. Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́. Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,” báyìí ní Olúwa wí. 33“Hasori yóò di ibi ìdọdẹ àwọn akátá, ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé, kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.” 34Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda. 35Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: “Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Elamu, ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.