Jeremiah 49:32
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ìbákasẹ á di ẹrù àti àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n á di ìkógun. Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́. Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,” báyìí ní Olúwa wí.
Jeremiah 49:32 in English
Jeremiah 49:32 · Berean Standard Bible
Their camels will become plunder, and their large herds will be spoil. I will scatter to the wind in every direction those who shave their temples; I will bring calamity on them from all sides,” declares the LORD.
Context
30“Sálọ kíákíá!
Fi ara pamọ́ sí ibi jíjìn, ẹ̀yin olùgbé Hasori,”
ni Olúwa wí.
“Nebukadnessari ọba Babeli ti dojú ìjà kọ ọ́. 31“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀-èdè tí ó wà nínú ìrọ̀rùn,
èyí tí ó gbé ní àìléwu,”
ní Olúwa wí.
“Orílẹ̀-èdè tí kò ní odi tàbí irin,
àwọn ènìyàn rẹ̀ ń dágbé. 32Àwọn ìbákasẹ á di ẹrù
àti àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n á di ìkógun.
Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́.
Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,”
báyìí ní Olúwa wí. 33“Hasori yóò di ibi ìdọdẹ àwọn akátá,
ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé,
kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.” 34Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.