Jeremiah 49:34
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda.
Jeremiah 49:34 in English
Jeremiah 49:34 · Berean Standard Bible
This is the word of the LORD that came to Jeremiah the prophet concerning Elam at the beginning of the reign of Zedekiah king of Judah.
Context
32Àwọn ìbákasẹ á di ẹrù
àti àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n á di ìkógun.
Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́.
Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,”
báyìí ní Olúwa wí. 33“Hasori yóò di ibi ìdọdẹ àwọn akátá,
ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé,
kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.” 34Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda. 35Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ:
“Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Elamu,
ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára. 36Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin
àgbáyé lòdì sí Elamu.
Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rin àti pé,
kò sí orílẹ̀-èdè
tí ilẹ̀ àjèjì Elamu kò ní lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.