Jeremiah 4:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí pé, “Àwọn ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn, àwọn àlùfáà yóò wárìrì, àwọn wòlíì yóò sì fòyà.”
Jeremiah 4:9 in English
Jeremiah 4:9 · Berean Standard Bible
“In that day,” declares the LORD, “the king and officials will lose their courage. The priests will tremble in fear, and the prophets will be astounded.”
Context
7Kìnnìún ti sá jáde láti inú ibùgbé rẹ̀,
apanirun orílẹ̀-èdè sì ti jáde.
Ó ti fi ààyè rẹ̀ sílẹ̀
láti ba ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́.
Ìlú rẹ yóò di ahoro
láìsí olùgbé. 8Nítorí náà, gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀
káàánú kí o sì pohùnréré ẹkún,
nítorí ìbínú ńlá Olúwa
kò tí ì kúrò lórí wa. 9“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí pé,
“Àwọn ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn,
àwọn àlùfáà yóò wárìrì,
àwọn wòlíì yóò sì fòyà.” 10Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jerusalẹmu jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o jẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.” 11Nígbà náà ni a ó sọ fún Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.