Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jerusalẹmu jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o jẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.”

Jeremiah 4:10 in English

Jeremiah 4:10 · Berean Standard Bible

Then I said, “Ah, Lord GOD, how completely You have deceived this people and Jerusalem by saying, ‘You will have peace,’ while a sword is at our throats.”

Context

8Nítorí náà, gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀ káàánú kí o sì pohùnréré ẹkún, nítorí ìbínú ńlá Olúwa kò tí ì kúrò lórí wa. 9“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí pé, “Àwọn ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn, àwọn àlùfáà yóò wárìrì, àwọn wòlíì yóò sì fòyà.” 10Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jerusalẹmu jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o jẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.” 11Nígbà náà ni a ó sọ fún Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́. 12Ẹ̀fúùfù líle tí ó wá láti ọ̀dọ̀ mi. Báyìí mo kéde ìdájọ́ mi lórí wọn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.