Jeremiah 4:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni a ó sọ fún Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́.
Jeremiah 4:11 in English
Jeremiah 4:11 · Berean Standard Bible
At that time it will be said to this people and to Jerusalem, “A searing wind from the barren heights in the desert blows toward the daughter of My people, but not to winnow or to sift;
Context
9“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí pé,
“Àwọn ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn,
àwọn àlùfáà yóò wárìrì,
àwọn wòlíì yóò sì fòyà.” 10Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jerusalẹmu jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o jẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.” 11Nígbà náà ni a ó sọ fún Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́. 12Ẹ̀fúùfù líle tí ó wá láti ọ̀dọ̀ mi. Báyìí mo kéde ìdájọ́ mi lórí wọn.” 13Wò ó! O ń bọ̀ bí ìkùùkuu
kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líle
ẹṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọ.
Ègbé ni fún wa àwa parun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.