Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wò ó! O ń bọ̀ bí ìkùùkuu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líle ẹṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọ. Ègbé ni fún wa àwa parun.

Jeremiah 4:13 in English

Jeremiah 4:13 · Berean Standard Bible

Behold, he advances like the clouds, his chariots like the whirlwind. His horses are swifter than eagles. Woe to us, for we are ruined!

Context

11Nígbà náà ni a ó sọ fún Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́. 12Ẹ̀fúùfù líle tí ó wá láti ọ̀dọ̀ mi. Báyìí mo kéde ìdájọ́ mi lórí wọn.” 13Wò ó! O ń bọ̀ bí ìkùùkuu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líle ẹṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọ. Ègbé ni fún wa àwa parun. 14Ìwọ Jerusalẹmu, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yè. Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ? 15Ohùn kan sì ń kéde ní Dani o ń kókìkí ìparun láti orí òkè Efraimu wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.