Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ohùn kan sì ń kéde ní Dani o ń kókìkí ìparun láti orí òkè Efraimu wá.

Jeremiah 4:15 in English

Jeremiah 4:15 · Berean Standard Bible

For a voice resounds from Dan, proclaiming disaster from the hills of Ephraim.

Context

13Wò ó! O ń bọ̀ bí ìkùùkuu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líle ẹṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọ. Ègbé ni fún wa àwa parun. 14Ìwọ Jerusalẹmu, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yè. Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ? 15Ohùn kan sì ń kéde ní Dani o ń kókìkí ìparun láti orí òkè Efraimu wá. 16“Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀-èdè, kéde rẹ̀ fún Jerusalẹmu pé: ‘Ọmọ-ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jíjìn wá wọ́n sì ń kígbe ogun láti dojúkọ ìlú Juda. 17Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá, nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.