Jeremiah 4:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá, nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ” ni Olúwa wí.
Jeremiah 4:17 in English
Jeremiah 4:17 · Berean Standard Bible
They surround her like men guarding a field, because she has rebelled against Me,” declares the LORD.
Context
15Ohùn kan sì ń kéde ní Dani
o ń kókìkí ìparun láti orí òkè Efraimu wá. 16“Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀-èdè,
kéde rẹ̀ fún Jerusalẹmu pé:
‘Ọmọ-ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jíjìn wá
wọ́n sì ń kígbe ogun láti dojúkọ ìlú Juda. 17Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá,
nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ”
ni Olúwa wí. 18“Ìwà rẹ àti ìṣe rẹ
ló fa èyí bá ọ
ìjìyà rẹ sì nìyìí.
Báwo ló ti ṣe korò tó!
Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!” 19Háà! Ìrora mi, ìrora mi!
Mo yí nínú ìrora.
Háà, ìrora ọkàn mi!
Ọkàn mi lù kìkì nínú mi,
n kò le è dákẹ́.
Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè,
mo sì ti gbọ́ igbe ogun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.