Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìwà rẹ àti ìṣe rẹ ló fa èyí bá ọ ìjìyà rẹ sì nìyìí. Báwo ló ti ṣe korò tó! Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!”

Jeremiah 4:18 in English

Jeremiah 4:18 · Berean Standard Bible

“Your ways and deeds have brought this upon you. This is your punishment; how bitter it is, because it pierces to the heart!”

Context

16“Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀-èdè, kéde rẹ̀ fún Jerusalẹmu pé: ‘Ọmọ-ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jíjìn wá wọ́n sì ń kígbe ogun láti dojúkọ ìlú Juda. 17Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá, nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ” ni Olúwa wí. 18“Ìwà rẹ àti ìṣe rẹ ló fa èyí bá ọ ìjìyà rẹ sì nìyìí. Báwo ló ti ṣe korò tó! Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!” 19Háà! Ìrora mi, ìrora mi! Mo yí nínú ìrora. Háà, ìrora ọkàn mi! Ọkàn mi lù kìkì nínú mi, n kò le è dákẹ́. Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè, mo sì ti gbọ́ igbe ogun. 20Ìparun ń gorí ìparun; gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparun lọ́gán ni a wó àwọn àgọ́ mi, tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.