Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìparun ń gorí ìparun; gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparun lọ́gán ni a wó àwọn àgọ́ mi, tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan.

Jeremiah 4:20 in English

Jeremiah 4:20 · Berean Standard Bible

Disaster after disaster is proclaimed, for the whole land is laid waste. My tents are destroyed in an instant, my curtains in a moment.

Context

18“Ìwà rẹ àti ìṣe rẹ ló fa èyí bá ọ ìjìyà rẹ sì nìyìí. Báwo ló ti ṣe korò tó! Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!” 19Háà! Ìrora mi, ìrora mi! Mo yí nínú ìrora. Háà, ìrora ọkàn mi! Ọkàn mi lù kìkì nínú mi, n kò le è dákẹ́. Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè, mo sì ti gbọ́ igbe ogun. 20Ìparun ń gorí ìparun; gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparun lọ́gán ni a wó àwọn àgọ́ mi, tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan. 21Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí ogun tí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè? 22“Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi; wọn kò mọ̀ mí. Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ; wọ́n sì jẹ́ aláìlóye. Wọ́n mọ ibi ni ṣíṣe; wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.