Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà. Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu. Orúkọ yìí ni a ó máa pè é Olúwa wa olódodo.’

Jeremiah 33:16 in English

Jeremiah 33:16 · Berean Standard Bible

In those days Judah will be saved, and Jerusalem will dwell securely, and this is the name by which it will be called: The LORD Our Righteousness.*

Context

14“ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Israẹli àti ilé Juda ṣẹ. 15“ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà, Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi. Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà. 16Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà. Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu. Orúkọ yìí ni a ó máa pè é Olúwa wa olódodo.’ 17Nítorí báyìí ni Olúwa wí: ‘Dafidi kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Israẹli. 18Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Lefi kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun; ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.