Jeremiah 33:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí báyìí ni Olúwa wí: ‘Dafidi kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Israẹli.
Jeremiah 33:17 in English
Jeremiah 33:17 · Berean Standard Bible
For this is what the LORD says: David will never lack a man to sit on the throne of the house of Israel,
Context
15“ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà,
Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi.
Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà. 16Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà.
Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu.
Orúkọ yìí ni a ó máa pè é
Olúwa wa olódodo.’ 17Nítorí báyìí ni Olúwa wí: ‘Dafidi kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Israẹli. 18Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Lefi kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun; ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ.’ ” 19Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá wí pé:
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.