Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà, Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi. Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà.

Jeremiah 33:15 in English

Jeremiah 33:15 · Berean Standard Bible

In those days and at that time I will cause to sprout for David a righteous Branch, and He will administer justice and righteousness in the land.

Context

13Ní ìlú òkè wọ̀n-ọn-nì, nínú ìlú àfonífojì, àti nínú ìlú ìhà gúúsù, àti ní ilẹ̀ ti Benjamini, ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda ni agbo àgùntàn yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni Olúwa wí. 14“ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Israẹli àti ilé Juda ṣẹ. 15“ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà, Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi. Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà. 16Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà. Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu. Orúkọ yìí ni a ó máa pè é Olúwa wa olódodo.’ 17Nítorí báyìí ni Olúwa wí: ‘Dafidi kò ní kùnà láti rí ọkùnrin tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ ní ilé Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.