Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ìlú òkè wọ̀n-ọn-nì, nínú ìlú àfonífojì, àti nínú ìlú ìhà gúúsù, àti ní ilẹ̀ ti Benjamini, ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda ni agbo àgùntàn yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni Olúwa wí.

Jeremiah 33:13 in English

Jeremiah 33:13 · Berean Standard Bible

In the cities of the hill country, the foothills,* and the Negev, in the land of Benjamin and the cities surrounding Jerusalem, and in the cities of Judah, the flocks will again pass under the hands of the one who counts them, says the LORD.

Context

11Ariwo ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé Olúwa wí pé: “ ‘ “Yin Olúwa àwọn ọmọ-ogun, nítorí Olúwa dára, ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé.” Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀,’ ni Olúwa wí. 12“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi. 13Ní ìlú òkè wọ̀n-ọn-nì, nínú ìlú àfonífojì, àti nínú ìlú ìhà gúúsù, àti ní ilẹ̀ ti Benjamini, ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda ni agbo àgùntàn yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni Olúwa wí. 14“ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Israẹli àti ilé Juda ṣẹ. 15“ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà, Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi. Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.