Jeremiah 33:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Israẹli àti ilé Juda ṣẹ.
Jeremiah 33:14 in English
Jeremiah 33:14 · Berean Standard Bible
Behold, the days are coming, declares the LORD, when I will fulfill the gracious promise that I have spoken to the house of Israel and the house of Judah.
Context
12“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi. 13Ní ìlú òkè wọ̀n-ọn-nì, nínú ìlú àfonífojì, àti nínú ìlú ìhà gúúsù, àti ní ilẹ̀ ti Benjamini, ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda ni agbo àgùntàn yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni Olúwa wí. 14“ ‘Àwọn ọjọ́ náà ń bọ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí èmi ó mú ìlérí rere tí mo ṣe fún ilé Israẹli àti ilé Juda ṣẹ. 15“ ‘Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àti ní àkókò náà,
Èmi ó gbé olódodo dìde láti ẹ̀ka Dafidi.
Yóò ṣe ìdájọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ilẹ̀ náà. 16Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà.
Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu.
Orúkọ yìí ni a ó máa pè é
Olúwa wa olódodo.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.