Jeremiah 31:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò tún gbé e yín sókè, àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli. Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé, ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.
Jeremiah 31:4 in English
Jeremiah 31:4 · Berean Standard Bible
Again I will build you, and you will be rebuilt, O Virgin Israel. Again you will take up your tambourines and go out in joyful dancing.
Context
2Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà
yóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀,
Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Israẹli.” 3Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé:
“Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin;
mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín, 4Èmi yóò tún gbé e yín sókè,
àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli.
Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé,
ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀. 5Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàrà
ní orí òkè Samaria;
àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa
gbádùn èso oko wọn. 6Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde
lórí òkè Efraimu wí pé,
‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni,
ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.