Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàrà ní orí òkè Samaria; àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa gbádùn èso oko wọn.

Jeremiah 31:5 in English

Jeremiah 31:5 · Berean Standard Bible

Again you will plant vineyards on the hills of Samaria; the farmers will plant and enjoy the fruit.

Context

3Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé: “Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin; mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín, 4Èmi yóò tún gbé e yín sókè, àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli. Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé, ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀. 5Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàrà ní orí òkè Samaria; àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa gbádùn èso oko wọn. 6Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde lórí òkè Efraimu wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni, ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ” 7Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé: “Ẹ fi ayọ̀ kọrin sí Jakọbu; ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo. Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé, ‘Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là; àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.