Jeremiah 31:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde lórí òkè Efraimu wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni, ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”
Jeremiah 31:6 in English
Jeremiah 31:6 · Berean Standard Bible
For there will be a day when watchmen will call out on the hills of Ephraim, ‘Arise, let us go up to Zion, to the LORD our God!’”
Context
4Èmi yóò tún gbé e yín sókè,
àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli.
Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé,
ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀. 5Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàrà
ní orí òkè Samaria;
àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa
gbádùn èso oko wọn. 6Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde
lórí òkè Efraimu wí pé,
‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni,
ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ” 7Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé:
“Ẹ fi ayọ̀ kọrin sí Jakọbu;
ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo.
Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé,
‘Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là;
àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli.’ 8Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá;
èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé.
Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ,
aboyún àti obìnrin tí ń rọbí,
ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.