Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín, èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni Olúwa wí, ‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri, Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’

Jeremiah 30:17 in English

Jeremiah 30:17 · Berean Standard Bible

But I will restore your health and heal your wounds, declares the LORD, because they call you an outcast, Zion, for whom no one cares.”

Context

15Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín, ìrora yín èyí tí kò ní oògùn? Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó ga ni mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín. 16“ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá, àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́. 17Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín, èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni Olúwa wí, ‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri, Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’ 18“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Èmi yóò dá gbogbo ìre àgọ́ Jakọbu padà, èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀; ìlú náà yóò sì di títúnṣe tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀. 19Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àti ìyìn yóò sì ti máa jáde. Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀, wọn kì yóò sì dínkù ní iye, Èmi yóò fi ọlá fún wọn, wọn kò sì ní di ẹni àbùkù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.