Jeremiah 30:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Èmi yóò dá gbogbo ìre àgọ́ Jakọbu padà, èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀; ìlú náà yóò sì di títúnṣe tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀.
Jeremiah 30:18 in English
Jeremiah 30:18 · Berean Standard Bible
This is what the LORD says: “I will restore the fortunes of * Jacob’s tents and have compassion on his dwellings. And the city will be rebuilt on her own ruins, and the palace will stand in its rightful place.
Context
16“ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá,
àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì;
gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́. 17Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín,
èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni Olúwa wí,
‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri,
Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’ 18“Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Èmi yóò dá gbogbo ìre àgọ́ Jakọbu padà,
èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀;
ìlú náà yóò sì di títúnṣe
tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀. 19Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àti
ìyìn yóò sì ti máa jáde.
Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀,
wọn kì yóò sì dínkù ní iye,
Èmi yóò fi ọlá fún wọn,
wọn kò sì ní di ẹni àbùkù. 20Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanì
níwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí.
Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára,
ni èmi yóò fì ìyà jẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.