Jeremiah 30:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá, àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.
Jeremiah 30:16 in English
Jeremiah 30:16 · Berean Standard Bible
Nevertheless, all who devour you will be devoured, and all your adversaries—every one of them— will go off into exile. Those who plundered you will be plundered, and all who raided you will be raided.
Context
14Gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ ti gbàgbé rẹ,
wọn kò sì náání rẹ mọ́ pẹ̀lú.
Mo ti nà ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá rẹ yóò ti nà ọ,
mo sì bá a ọ wí gẹ́gẹ́ bí ìkà,
nítorí tí ẹ̀bi rẹ pọ̀ púpọ̀,
ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lóǹkà. 15Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín,
ìrora yín èyí tí kò ní oògùn?
Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó ga
ni mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín. 16“ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá,
àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì;
gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́. 17Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín,
èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni Olúwa wí,
‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri,
Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’ 18“Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Èmi yóò dá gbogbo ìre àgọ́ Jakọbu padà,
èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀;
ìlú náà yóò sì di títúnṣe
tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.