Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ ti gbàgbé rẹ, wọn kò sì náání rẹ mọ́ pẹ̀lú. Mo ti nà ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá rẹ yóò ti nà ọ, mo sì bá a ọ wí gẹ́gẹ́ bí ìkà, nítorí tí ẹ̀bi rẹ pọ̀ púpọ̀, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lóǹkà.

Jeremiah 30:14 in English

Jeremiah 30:14 · Berean Standard Bible

All your lovers have forgotten you; they no longer seek you, for I have struck you as an enemy would, with the discipline of someone cruel, because of your great iniquity and your numerous sins.

Context

12“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn, bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn. 13Kò sí ẹnìkan tí yóò bẹ̀bẹ̀ fún àìṣedéédéé yín, kò sí ètùtù fún ọgbẹ́ yín, a kò sì mú yín láradá. 14Gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ ti gbàgbé rẹ, wọn kò sì náání rẹ mọ́ pẹ̀lú. Mo ti nà ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá rẹ yóò ti nà ọ, mo sì bá a ọ wí gẹ́gẹ́ bí ìkà, nítorí tí ẹ̀bi rẹ pọ̀ púpọ̀, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lóǹkà. 15Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín, ìrora yín èyí tí kò ní oògùn? Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó ga ni mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín. 16“ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá, àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.