Jeremiah 25:30
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nísinsin yìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn: “ ‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá, yóò sì bú kíkankíkan sí ilẹ̀ náà. Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí.
Jeremiah 25:30 in English
Jeremiah 25:30 · Berean Standard Bible
So you are to prophesy all these words against them and say to them: ‘The LORD will roar from on high; He will raise His voice from His holy habitation. He will roar loudly over His pasture; like those who tread the grapes, He will call out with a shout against all the inhabitants of the earth.
Context
28Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba ago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: Ẹyin gbọdọ̀ mu ún! 29Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀-èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò ha a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’ 30“Nísinsin yìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn:
“ ‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá,
yóò sì bú kíkankíkan sí ilẹ̀ náà.
Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí. 31Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé,
nítorí pé Olúwa yóò mú ìdààmú wá sí orí
àwọn orílẹ̀-èdè náà,
yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn,
yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’ ”
ni Olúwa wí. 32Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn;
ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.