Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀-èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò ha a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’

Jeremiah 25:29 in English

Jeremiah 25:29 · Berean Standard Bible

For behold, I am beginning to bring disaster on the city that bears My Name, so how could you possibly go unpunished? You will not go unpunished, for I am calling down a sword upon all the inhabitants of the earth, declares the LORD of Hosts.’

Context

27“Nígbà náà, sọ fún wọn, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli wí. Mu, kí o sì mú àmuyó kí o sì bì, bẹ́ẹ̀ ni kí o sì ṣubú láì dìde mọ́ nítorí idà tí n ó rán sí àárín yín. 28Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba ago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: Ẹyin gbọdọ̀ mu ún! 29Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀-èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò ha a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’ 30“Nísinsin yìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn: “ ‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá, yóò sì bú kíkankíkan sí ilẹ̀ náà. Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí. 31Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé, nítorí pé Olúwa yóò mú ìdààmú wá sí orí àwọn orílẹ̀-èdè náà, yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn, yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’ ” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.