Jeremiah 25:31
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé, nítorí pé Olúwa yóò mú ìdààmú wá sí orí àwọn orílẹ̀-èdè náà, yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn, yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’ ” ni Olúwa wí.
Jeremiah 25:31 in English
Jeremiah 25:31 · Berean Standard Bible
The tumult will resound to the ends of the earth because the LORD brings a charge against the nations. He brings judgment on all mankind and puts the wicked to the sword,’” declares the LORD.
Context
29Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀-èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò ha a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’ 30“Nísinsin yìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn:
“ ‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá,
yóò sì bú kíkankíkan sí ilẹ̀ náà.
Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí. 31Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé,
nítorí pé Olúwa yóò mú ìdààmú wá sí orí
àwọn orílẹ̀-èdè náà,
yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn,
yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’ ”
ni Olúwa wí. 32Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn;
ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé.” 33Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.