Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a wọ́ sọnù láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu.”

Jeremiah 22:19 in English

Jeremiah 22:19 · Berean Standard Bible

He will be buried like a donkey, dragged away and thrown outside the gates of Jerusalem.

Context

17“Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ wà lára èrè àìṣòótọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.” 18Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda: “Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’ Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’ 19A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a wọ́ sọnù láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu.” 20“Gòkè lọ sí Lebanoni, kígbe síta, kí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Baṣani, kí o kígbe sókè láti Abarimu, nítorí a ti ṣẹ́ gbogbo olùfẹ́ rẹ túútúú. 21Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu, ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’ Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ, ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.