Jeremiah 22:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Gòkè lọ sí Lebanoni, kígbe síta, kí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Baṣani, kí o kígbe sókè láti Abarimu, nítorí a ti ṣẹ́ gbogbo olùfẹ́ rẹ túútúú.
Jeremiah 22:20 in English
Jeremiah 22:20 · Berean Standard Bible
Go up to Lebanon and cry out; raise your voice in Bashan; cry out from Abarim, for all your lovers have been crushed.
Context
18Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:
“Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:
wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’
Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:
wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’ 19A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
tí a wọ́ sọnù láti ẹnu ibodè
Jerusalẹmu.” 20“Gòkè lọ sí Lebanoni, kígbe síta,
kí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Baṣani,
kí o kígbe sókè láti Abarimu,
nítorí a ti ṣẹ́ gbogbo olùfẹ́ rẹ túútúú. 21Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu,
ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’
Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ,
ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́. 22Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ,
gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbèkùn,
nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́
nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.