Jeremiah 22:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ wà lára èrè àìṣòótọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”
Jeremiah 22:17 in English
Jeremiah 22:17 · Berean Standard Bible
“But your eyes and heart are set on nothing except your own dishonest gain, on shedding innocent blood, on practicing extortion and oppression.”
Context
15“Ìwọ ó ha jẹ ọba
kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari?
Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu?
Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo,
nítorí náà ó dára fún un. 16Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní,
ohun gbogbo sì dára fún un.
Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?”
ni Olúwa wí. 17“Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ
wà lára èrè àìṣòótọ́
láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀
ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.” 18Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:
“Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:
wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’
Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:
wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’ 19A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
tí a wọ́ sọnù láti ẹnu ibodè
Jerusalẹmu.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.