Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní, ohun gbogbo sì dára fún un. Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?” ni Olúwa wí.

Jeremiah 22:16 in English

Jeremiah 22:16 · Berean Standard Bible

He took up the cause of the poor and needy, and so it went well with him. Is this not what it means to know Me?” declares the LORD.

Context

14Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara mi àwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀, ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’ A ó sì fi igi kedari bò ó, a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́. 15“Ìwọ ó ha jẹ ọba kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari? Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu? Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo, nítorí náà ó dára fún un. 16Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní, ohun gbogbo sì dára fún un. Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?” ni Olúwa wí. 17“Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ wà lára èrè àìṣòótọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.” 18Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda: “Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’ Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.