Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìwọ ó ha jẹ ọba kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari? Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu? Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo, nítorí náà ó dára fún un.

Jeremiah 22:15 in English

Jeremiah 22:15 · Berean Standard Bible

Does it make you a king to excel * in cedar? Did not your father have food and drink? He administered justice and righteousness, and so it went well with him.

Context

13“Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo, àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn. 14Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara mi àwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀, ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’ A ó sì fi igi kedari bò ó, a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́. 15“Ìwọ ó ha jẹ ọba kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari? Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu? Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo, nítorí náà ó dára fún un. 16Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní, ohun gbogbo sì dára fún un. Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?” ni Olúwa wí. 17“Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ wà lára èrè àìṣòótọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.