Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo, àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn.

Jeremiah 22:13 in English

Jeremiah 22:13 · Berean Standard Bible

“Woe to him who builds his palace by unrighteousness, and his upper rooms without justice, who makes his countrymen serve without pay, and fails to pay their wages,

Context

11Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣallumu ọmọ Josiah ọba Juda tí ó jẹ ọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn-ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́. 12Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.” 13“Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo, àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn. 14Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara mi àwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀, ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’ A ó sì fi igi kedari bò ó, a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́. 15“Ìwọ ó ha jẹ ọba kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari? Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu? Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo, nítorí náà ó dára fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.