Jeremiah 22:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.”
Jeremiah 22:12 in English
Jeremiah 22:12 · Berean Standard Bible
but he will die in the place to which he was exiled; he will never see this land again.”
Context
10Nítorí náà má ṣe sọkún nítorí ọba tí ó ti kú tàbí ṣọ̀fọ̀ fún àdánù rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹ sọkún kíkorò fún ẹni tí a lé kúrò nílùú
nítorí kì yóò padà wá mọ́
tàbí fi ojú rí ilẹ̀ tí a ti bí i. 11Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣallumu ọmọ Josiah ọba Juda tí ó jẹ ọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn-ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́. 12Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.” 13“Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo,
àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́
tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán
láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn. 14Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara mi
àwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀,
ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’
A ó sì fi igi kedari bò ó,
a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.